Ìbẹ̀rẹ̀ (Fàtíyà)
By Adeniyi Ade Adeleke
Sat, 01-Sep-2018, 01:46

Ní orúkọ Olódùmaré, 

Onínú rere jùlọ, Aláàánú jùlọ.

Ti Olódùmaré ni ọpẹ, 

Olúwa ẹdá gbogbo. 

Onínú rere jùlọ, Aláàánú jùlọ.

Olúwa ọjọ ìdàjọ.

Ìwọ ni ọkan tí àwa yóò máa sìn, 

ọdọ rẹ ni àwa yóò ti ma wá ìrànlọwọ. 

Tọ àwa sí ọnà tí ó tọ,

Ọnà àwọn tí ó ti rí ojú rere rẹ,

èyí tí kì ṣe ọnà àwọn tí ó ti rí ìbínú rẹ 

èyí tí kì ṣe ọnà àwọn tí ó ti ṣì ọnà.


Share via:

Leave a Message: